9. OLUWA ní kí wọn sọ fún Sedekaya ati àwọn ará Juda kí wọn má tan ara wọn jẹ, kí wọn má sì rò pé àwọn ará Kalidea kò ní pada wá sọ́dọ̀ wọn mọ́, nítorí wọn kò ní lọ.
10. Bí àwọn ará Juda bá tilẹ̀ ṣẹgun gbogbo ọmọ ogun àwọn ará Kalidea, tí wọ́n gbógun tì wọ́n, títí tí ó fi jẹ́ pé àwọn tí wọ́n ti fara gbọgbẹ́ nìkan ni wọ́n kù ninu àgọ́ wọn, wọn yóo dìde sí àwọn ará Juda, wọn yóo sì sun ìlú yìí níná.
11. Lẹ́yìn tí àwọn ọmọ ogun Kalidea ti kúrò ní Jerusalẹmu, nígbà tí wọ́n rí i pé àwọn ọmọ ogun Farao ń bọ̀,
12. Jeremaya jáde ní Jerusalẹmu ó fẹ́ lọ sí ilẹ̀ Bẹnjamini kí ó lọ gba ilẹ̀ rẹ̀ kan lọ́wọ́ àwọn eniyan tí wọ́n wà níbẹ̀.
13. Bí Jeremaya wolii ti dé bodè Bẹnjamini ọ̀kan ninu àwọn oníbodè tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Irija ọmọ Ṣelemaya ọmọ Hananaya mú un, ó ní, “O fẹ́ sálọ bá àwọn ará Kalidea ni.”
14. Jeremaya dá a lóhùn, pé, “Rárá o, n kò sálọ sọ́dọ̀ àwọn ará Kalidea.” Ṣugbọn Irija kọ̀, kò gbọ́, ó sá mú Jeremaya lọ sọ́dọ̀ àwọn ìjòyè.
15. Inú bí àwọn ìjòyè sí Jeremaya, wọ́n lù ú, wọ́n sì jù ú sẹ́wọ̀n ní ilé Jonatani akọ̀wé, nítorí pé wọ́n ti sọ ibẹ̀ di ọgbà ẹ̀wọ̀n.
16. Lẹ́yìn tí Jeremaya ti wà ní ọgbà ẹ̀wọ̀n fún ọpọlọpọ ọjọ́,
17. Sedekaya ọba ranṣẹ lọ mú un wá sí ààfin rẹ̀, ó sì fi ọ̀rọ̀ wá a lẹ́nu wò níkọ̀kọ̀, ó ní, “Ǹjẹ́ OLUWA ranṣẹ kankan?”Jeremaya dáhùn, ó ní, “Bẹ́ẹ̀ ni, ohun tí OLUWA sọ ni pé, a óo fi ọ́ lé ọba Babiloni lọ́wọ́.”
18. Jeremaya wá bi Sedekaya ọba pé, “Ẹ̀ṣẹ̀ wo ni mo ṣẹ̀ ọ́, tabi àwọn ẹmẹ̀wà rẹ, tabi àwọn ará ìlú yìí, tí ẹ fi jù mí sẹ́wọ̀n?