5. Àwọn ọmọ ogun Farao ti jáde, wọ́n ń bọ̀ láti Ijipti; nígbà tí àwọn ará Kalidea tí wọn dóti Jerusalẹmu gbọ́ pé wọ́n ń bọ̀, wọ́n kúrò ní Jerusalẹmu.
6. OLUWA sọ fún Jeremaya wolii pé kí ó sọ fún àwọn tí ọba Juda rán láti wá wádìí ọ̀rọ̀ lọ́wọ́ rẹ̀ pé,
7. OLUWA Ọlọrun Israẹli ní kí òun Jeremaya sọ fún ọba pé, àwọn ọmọ ogun Farao tí wọn wá ràn wọ́n lọ́wọ́ ti ń múra láti pada sí Ijipti, ilẹ̀ wọn.