Jeremaya 32:17-27 BIBELI MIMỌ (BM)

17. ‘OLUWA, Ọlọrun! Ìwọ tí o dá ọ̀run ati ayé pẹlu agbára ńlá ati ipá rẹ! Kò sí ohun tí ó ṣòro fún ọ,

18. ìwọ tí ò ń fi ìfẹ́ rẹ tí kì í yẹ̀ hàn fún ẹgbẹẹgbẹrun eniyan, ṣugbọn tí ò ń gba ẹ̀san àwọn baba lára àwọn ọmọ wọn lẹ́yìn ikú wọn, ìwọ Ọlọrun alágbára ńlá tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ OLUWA àwọn ọmọ ogun,

19. ìwọ Olùdámọ̀ràn ńlá, tí ó lágbára ní ìṣe; ìwọ tí ojú rẹ ń rí sí gbogbo ọ̀nà àwọn ọmọ eniyan, tí o sì ń san ẹ̀san fún olukuluku gẹ́gẹ́ bí ìwà ati iṣẹ́ ọwọ́ rẹ̀;

20. ìwọ tí o ṣe iṣẹ́ abàmì, ati iṣẹ́ ìyanu ní ilẹ̀ Ijipti, o sì tún ń ṣe iṣẹ́ náà títí di òní ní Israẹli ati láàrin gbogbo eniyan; o sì ti fìdí orúkọ rẹ múlẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ó ti rí lónìí.

21. Ìwọ ni o kó àwọn ọmọ Israẹli, àwọn eniyan rẹ, jáde láti ilẹ̀ Ijipti pẹlu iṣẹ́ abàmì ati iṣẹ́ ìyanu, pẹlu ọwọ́ agbára, ipá ati ìbẹ̀rù ńlá.

22. O sì fún wọn ní ilẹ̀ yìí, ilẹ̀ tí o búra fún àwọn baba ńlá wọn pé o óo fún wọn, ilẹ̀ tí ó kún fún wàrà ati oyin.

23. Wọ́n dé ilẹ̀ náà, wọ́n sì gbà á; ṣugbọn wọn kò gbọ́rọ̀ sí ọ lẹ́nu, wọn kò sì pa òfin rẹ mọ́. Wọn kò ṣe ọ̀kan kan ninu gbogbo ohun tí o pàṣẹ fún wọn láti máa ṣe; nítorí náà ni o ṣe mú kí gbogbo ibi tí ó ṣẹlẹ̀ sí wọn bá wọn!

24. “ ‘Wo bí àwọn ọ̀tá ti mọ òkítì sí ara odi wa láti gba ìlú wa. Nítorí ogun, ìyàn ati àjàkálẹ̀ àrùn, a óo fi ìlú yìí lé àwọn ará Kalidea tí wọn gbógun tì í lọ́wọ́. Ohun tí o wí ṣẹ, o sì ti rí i.

25. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé a ti fi ìlú yìí lé àwọn ará Kalidea lọ́wọ́, sibẹsibẹ, ìwọ OLUWA Ọlọrun ni o sọ fún mi pé kí n ra ilẹ̀, kí n sì ní àwọn ẹlẹ́rìí.’ ”

26. OLUWA sọ fún Jeremaya pé,

27. “Wò ó! Èmi ni OLUWA, Ọlọrun gbogbo eniyan, ǹjẹ́ nǹkankan wà tí ó ṣòro fún mi láti ṣe?

Jeremaya 32