32. Kì í ṣe irú majẹmu tí mo bá àwọn baba ńlá wọn dá, ní ìgbà tí mo fà wọ́n lọ́wọ́ jáde ní ilẹ̀ Ijipti, àní majẹmu mi tí wọn dà, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé èmi ni ọkọ wọn.
33. Ṣugbọn majẹmu tí n óo bá ilé Israẹli dá nígbà tó bá yá nìyí: N óo fi òfin mi sí inú wọn, n óo sì kọ wọ́n sí ọkàn wọn. N óo máa jẹ́ Ọlọrun wọn, wọn yóo sì máa jẹ́ eniyan mi.
34. Ẹnikẹ́ni kò ní máa kọ́ aládùúgbò rẹ̀ tabi arakunrin rẹ̀ bí a ti í mọ èmi OLUWA mọ́, gbogbo wọn ni wọn yóo mọ̀ mí ati àwọn mẹ̀kúnnù ati àwọn eniyan pataki pataki. N óo dárí ẹ̀ṣẹ̀ wọn jì wọ́n, n kò sì ní ranti àìdára wọn mọ́. Èmi OLUWA ni mo sọ bẹ́ẹ̀.”
35. OLUWA ni ó dá oòrùn, láti máa ràn ní ọ̀sán,tí ó fún òṣùpá ati ìràwọ̀ láṣẹ, láti tan ìmọ́lẹ̀ lálẹ́,tí ó rú omi òkun sókè, tí ìgbì rẹ̀ ń hó yaya,òun ni orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ OLUWA àwọn ọmọ ogun.
36. Òun ló sọ pé, àfi bí àwọn àṣẹ wọnyi bá yipada níwájú òun,ni àwọn ọmọ Israẹli kò fi ní máa jẹ́ orílẹ̀-èdè títí lae.
37. Àfi bí eniyan bá lè wọn ojú ọ̀run,tí ó sì lè wádìí ìpìlẹ̀ ayé,ni òun lè ké àwọn ọmọ Israẹli kúrò,nítorí gbogbo ohun tí wọ́n ṣe.
38. OLUWA ni, “Ẹ wò ó! Àkókò ń bọ̀ tí a óo tún Jerusalẹmu kọ́ fún mi láti ilé ìṣọ́ Hananeli títí dé Bodè Igun.
39. A óo ta okùn ìwọ̀n odi ìlú títí dé òkè Garebu, ati títí dé Goa pẹlu.
40. Gbogbo àfonífojì tí wọn ń da òkú ati eérú sí, ati gbogbo pápá títí dé odò Kidironi, dé ìkangun Bodè Ẹṣin, ní ìhà ìlà oòrùn, ni yóo jẹ́ ibi mímọ́ fún OLUWA. Wọn kò ní fọ́ ọ mọ́, ẹnìkan kò sì ní wó o lulẹ̀ títí laelae.”