Jeremaya 31:1-8 BIBELI MIMỌ (BM)

1. OLUWA ní, “Àkókò ń bọ̀ tí n óo jẹ́ Ọlọrun gbogbo ìdílé Israẹli,tí àwọn náà yóo sì jẹ́ eniyan mi.

2. Àwọn tí wọ́n bọ́ lọ́wọ́ idà, rí àánú OLUWA ninu aṣálẹ̀;nígbà tí Israẹli ń wá ìsinmi,

3. OLUWA yọ sí wọn láti òkèèrè.Ìfẹ́ àìlópin ni mo ní sí ọ,nítorí náà n kò ní yé máa fi òtítọ́ bá ọ lò.

4. N óo tún yín gbé dìde, ẹ óo sì di ọ̀tun, ẹ̀yin ọmọ Israẹli.Ẹ óo tún fi aro lu ìlù ayọ̀, ẹ óo sì jó ijó ìdùnnú.

5. Ẹ óo tún ṣe ọgbà àjàrà sórí òkè Samaria;àwọn tí wọ́n gbin àjàrà ni yóo sì gbádùn èso orí rẹ̀.

6. Nítorí pé ọjọ́ kan ń bọ̀, tí àwọn aṣọ́nà yóo pè yín láti orí òkè Efuraimu pé,‘Ẹ dìde, ẹ jẹ́ kí á lọ sí òkè Sioni,sí ọ̀dọ̀ OLUWA Ọlọrun wa.’ ”

7. OLUWA ní,“Ẹ kọ orin sókè pẹlu ìdùnnú fún Jakọbu,kí ẹ sì hó fún olórí àwọn orílẹ̀-èdè,ẹ kéde, ẹ kọ orin ìyìn, kí ẹ sì wí pé,‘OLUWA ti gba àwọn eniyan rẹ̀ lààní, àwọn eniyan Israẹli yòókù.’

8. Ẹ wò ó! N óo kó wọn wá láti ilẹ̀ àríwá,n óo kó wọn jọ láti òpin ayé.Àwọn afọ́jú ati arọ yóo wà láàrin wọn,ati aboyún ati àwọn tí wọn ń rọbí lọ́wọ́.Ogunlọ́gọ̀ eniyan ni àwọn tí yóo pada wá síbí.

Jeremaya 31