Jeremaya 30:21-24 BIBELI MIMỌ (BM)

21. Ọ̀kan ninu wọn ni yóo jọba lórí wọn,ààrin wọn ni a óo sì ti yan olórí wọn;n óo fà á mọ́ra, yóo sì súnmọ́ mi,nítorí pé kò sí ẹni tí ó lè fúnra rẹ̀ súnmọ́ mi.Èmi OLUWA ni mo sọ bẹ́ẹ̀.

22. Ẹ óo jẹ́ eniyan mi, n óo sì jẹ́ Ọlọrun yín.”

23. Ẹ wo ìjì OLUWA!Ibinu rẹ̀ ń bọ̀ bí ìjì líle.Ó ń bọ̀ sórí àwọn oníṣẹ́ ibi.

24. Ibinu gbígbóná OLUWA kò ní yipada,títí yóo fi mú èrò ọkàn rẹ̀ ṣẹ.Òye nǹkan wọnyi yóo ye yín ní ọjọ́ ìkẹyìn.

Jeremaya 30