5. Jeremaya wolii bá dá Hananaya wolii lóhùn níṣojú àwọn alufaa ati gbogbo àwọn ará ìlú tí wọn dúró ní ilé OLUWA,
6. ó ní, “Amin, kí OLUWA ṣe bẹ́ẹ̀. Kí OLUWA mú àsọtẹ́lẹ̀ tí o sọ ṣẹ, kí ó kó àwọn ohun èlò ilé rẹ̀ ati gbogbo àwọn eniyan tí a kó lẹ́rú lọ sí Babiloni pada sí ibí yìí.
7. Ṣugbọn gbọ́ ohun tí n óo sọ fún ìwọ ati gbogbo àwọn eniyan wọnyi.
8. Àwọn wolii tí wọ́n ti wà ṣáájú èmi pẹlu rẹ ní ìgbà àtijọ́ sọ àsọtẹ́lẹ̀ ogun, ìyàn, ati àjàkálẹ̀ àrùn nípa ọpọlọpọ orílẹ̀-èdè ati nípa àwọn ìjọba ńláńlá.
9. Wolii tí ó bá fẹ́ sọ àsọtẹ́lẹ̀ pé alaafia yóo wà, nígbà tí ọ̀rọ̀ wolii náà bá ṣẹ ni a óo mọ̀ pé OLUWA ni ó rán an níṣẹ́ nítòótọ́.”
10. Hananaya wolii bá bọ́ àjàgà kúrò lọ́rùn Jeremaya, ó sì ṣẹ́ ẹ.