4. Òun óo mú Jehoiakini ọba Juda, ọmọ Jehoiakimu, ati gbogbo àwọn tí a kó lẹ́rú láti Juda lọ sí Babiloni pada sí ibí yìí, nítorí òun óo ṣẹ́ àjàgà ọba Babiloni. Ó ní OLUWA ló sọ bẹ́ẹ̀.”
5. Jeremaya wolii bá dá Hananaya wolii lóhùn níṣojú àwọn alufaa ati gbogbo àwọn ará ìlú tí wọn dúró ní ilé OLUWA,
6. ó ní, “Amin, kí OLUWA ṣe bẹ́ẹ̀. Kí OLUWA mú àsọtẹ́lẹ̀ tí o sọ ṣẹ, kí ó kó àwọn ohun èlò ilé rẹ̀ ati gbogbo àwọn eniyan tí a kó lẹ́rú lọ sí Babiloni pada sí ibí yìí.