1. Ní ìbẹ̀rẹ̀ ìjọba Sedekaya, ọba Juda, ọmọ Josaya, OLUWA bá èmi Jeremaya sọ̀rọ̀; ó ní:
2. “Ṣe àjàgà kan pẹlu okùn rẹ̀ kí o sì fi bọ ara rẹ lọ́rùn.
3. Àwọn ikọ̀ kan wá sí ọ̀dọ̀ Sedekaya, ọba Juda, ní Jerusalẹmu, láti ọ̀dọ̀ ọba Edomu ati ọba Moabu, ọba àwọn ọmọ Amoni, ọba Tire, ati ọba Sidoni wá, rán wọn pada sí àwọn oluwa wọn,
4. sì pàṣẹ fún wọn pé kí wọ́n sọ fún wọn pé OLUWA àwọn ọmọ ogun, Ọlọrun Israẹli ní