“Nítorí náà, sọ àsọtẹ́lẹ̀ yìí fún wọn pé:‘OLUWA yóo bú ramúramù láti òkè,yóo pariwo láti ibi mímọ́ rẹ̀.Yóo bú ramúramù mọ́ àwọn eniyan inú agbo rẹ̀.Yóo kígbe mọ́ gbogbo aráyé bí igbe àwọn tí ń tẹ àjàrà.