1. Ọ̀rọ̀ tí Jeremaya gbọ́ lẹ́nu OLUWA nìyí nígbà tí ọba Sedekaya rán Paṣuri, ọmọ Malikaya, ati alufaa Sefanaya, ọmọ Maaseaya, sí i;
2. tí ọba Sedekaya ní, “Ẹ sọ fún Jeremaya pé kí ó bá wa ṣe ìwádìí lọ́dọ̀ OLUWA nípa Nebukadinesari, ọba Babiloni, tí ó gbógun tì wá; bóyá OLUWA yóo ṣe iṣẹ́ ìyanu rẹ̀ fún wa, kí Nebukadinesari kó àwọn ọmọ ogun rẹ̀ kúrò ní ilẹ̀ wa.”
3. Jeremaya sọ fun awọn tí wọn rán sí i,
4. kí wọ́n sọ fún Sedekaya pé OLUWA Ọlọrun Israẹli ní, “N óo gba àwọn ohun ìjà tí ó wà lọ́wọ́ yín, tí ẹ fi ń bá ọba Babiloni ati àwọn ará Kalidea tí wọn gbógun tì yín lẹ́yìn odi jà, n óo dá wọn pada sí ààrin ìlú, n óo sì dojú wọn kọ yín.
5. Èmi fúnra mi ni n óo ba yín jà. Ipá ati agbára, pẹlu ibinu ńlá, ati ìrúnú gbígbóná ni n óo fi ba yín jà.
6. N óo fi àjàkálẹ̀ àrùn ńlá kọlu àwọn ará ìlú yìí, ati eniyan ati ẹranko ni yóo sì kú.