1. OLUWA bá Jeremaya sọ̀rọ̀, ó ní:
2. “Dìde, lọ sí ilé amọ̀kòkò, níbẹ̀ ni óo ti gbọ́ ọ̀rọ̀ tí mo fẹ́ bá ọ sọ.”
3. Mo bá lọ sí ilé amọ̀kòkò. Mo bá a tí ó ń mọ ìkòkò kan lórí òkúta tí wọn fi ń mọ ìkòkò.
4. Ìkòkò tí ó ń fi amọ̀ mọ bàjẹ́ lọ́wọ́ rẹ̀, ó bá fi amọ̀ náà mọ ìkòkò mìíràn, tí ó wù ú.
5. OLUWA bá sọ fún mi pé,
6. “Ẹ̀yin ilé Israẹli, ṣé n kò lè ṣe yín bí amọ̀kòkò yìí ti ṣe ìkòkò tí ó mọ ni? Bí amọ̀ ti rí lọ́wọ́ amọ̀kòkò ni ẹ rí lọ́wọ́ mi, ẹ̀yin ilé Israẹli.
7. Bí mo bá sọ pé n óo fa orílẹ̀-èdè kan, tabi ìjọba kan tu, n óo wó o lulẹ̀, n óo sì pa á run,
8. bí orílẹ̀-èdè ọ̀hún bá yipada kúrò ninu ìwà burúkú rẹ̀, n óo dá ibi tí mo ti fẹ́ ṣe sí i tẹ́lẹ̀ dúró.
9. Bí mo bá sọ pé n óo gbé orílẹ̀-èdè kan dìde, n óo sì fi ìdí rẹ̀ múlẹ̀;
10. bí ó bá ṣe nǹkan burúkú lójú mi, tí kò gbọ́ràn sí mi lẹ́nu, n óo dá nǹkan rere tí mo ti fẹ́ ṣe fún un dúró.