3. ati lórí àwọn òkè ninu pápá. N óo sọ gbogbo ọrọ̀ yín ati gbogbo ohun ìṣúra yín di ìkógun fún àwọn ọ̀tá yín; n óo fi gbẹ̀san ẹ̀ṣẹ̀ yín ní gbogbo ilẹ̀ yín.
4. Ìwà yín yóo mú kí ilẹ̀ tí mo fun yín bọ́ lọ́wọ́ yín; n óo sí sọ yín di ẹrú àwọn ọ̀tá yín ní ilẹ̀ tí ẹ kò mọ̀rí. Ẹ ti mú kí ibinu mi máa jó bí iná, kò sì ní kú títí lae.”
5. OLUWA ní,“Ègún ni fún ẹni tí ó bá gbẹ́kẹ̀lé eniyan,tí ó fi ẹlẹ́ran ara ṣe agbára rẹ̀;tí ọkàn rẹ̀ yipada kúrò lọ́dọ̀ èmi OLUWA.
6. Ó dàbí igbó ṣúúrú ninu aṣálẹ̀,nǹkan rere kan kò lè ṣẹlẹ̀ sí i.Ninu ilẹ̀ gbígbẹ, ninu aṣálẹ̀ ni ó wà,ninu ilẹ̀ iyọ̀ tí ẹnikẹ́ni kò lè gbé.