19. Nítorí náà OLUWA ní, “Bí o bá yipada, n óo mú ọ pada sípò rẹ, o óo sì tún máa ṣe iranṣẹ mi. Bí o bá bẹ̀rẹ̀ sí sọ ọ̀rọ̀ gidi, tí o dákẹ́ ìsọkúsọ, o óo tún pada di òjíṣẹ́ mi. Àwọn ni yóo pada tọ̀ ọ́ wá, o kò ní tọ̀ wọ́n lọ.
20. N óo sọ ọ́ di odi alágbára tí a fi idẹ mọ, lọ́dọ̀ àwọn eniyan wọnyi. Wọn yóo gbógun tì ọ́, ṣugbọn wọn kò ní ṣẹgun rẹ, nítorí pé mo wà pẹlu rẹ láti gbà ọ́, ati láti yọ ọ́. Èmi OLUWA ni mo sọ bẹ́ẹ̀.
21. N óo gbà ọ́ lọ́wọ́ àwọn eniyan burúkú, n óo sì rà ọ́ pada lọ́wọ́ àwọn ìkà, aláìláàánú eniyan.”