N óo sọ ọ́ di odi alágbára tí a fi idẹ mọ, lọ́dọ̀ àwọn eniyan wọnyi. Wọn yóo gbógun tì ọ́, ṣugbọn wọn kò ní ṣẹgun rẹ, nítorí pé mo wà pẹlu rẹ láti gbà ọ́, ati láti yọ ọ́. Èmi OLUWA ni mo sọ bẹ́ẹ̀.