Jeremaya 14:5-11 BIBELI MIMỌ (BM)

5. Àgbọ̀nrín inú igbó pàápàá já ọmọ tí ó ṣẹ̀ṣẹ̀ bí sílẹ̀,nítorí kò sí koríko.

6. Àwọn kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ igbó dúró lórí òkè,wọ́n ń mí hẹlẹhẹlẹ bí ajáko.Ojú wọn rẹ̀wẹ̀sì, nítorí kò sí koríko.

7. Àwọn eniyan mi ké pè mí wí pé,‘Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ẹ̀ṣẹ̀ wa ń jẹ́rìí lòdì sí wa,sibẹsibẹ, nítorí orúkọ rẹ, gbà wá.Ọpọlọpọ ìgbà ni a ti pada lẹ́yìn rẹ,a ti ṣẹ̀ ọ́.

8. Ìwọ ìrètí Israẹli,olùgbàlà rẹ̀ ní ìgbà ìṣòro.Kí ló dé tí o óo fi dàbí àlejò ní ilẹ̀ náà?Àní, bí èrò ọ̀nà, tí ó yà láti sùn mọ́jú?

9. Kí ló dé tí o fi dàbí ẹni tí ìdààmú bá;bí alágbára tí kò lè gbani là?Bẹ́ẹ̀ ni o wà láàrin wa, OLUWA,a sì ń fi orúkọ rẹ pè wá,má fi wá sílẹ̀.’ ”

10. OLUWA sọ nípa àwọn eniyan náà pé,“Ó wù wọ́n láti máa ṣáko kiri,wọn kò ṣọ́ ìrìn ẹsẹ̀ wọn;nítorí náà wọn kì í ṣe ìtẹ́wọ́gbà lọ́dọ̀ OLUWA,nisinsinyii OLUWA yóo ranti àìdára wọn,yóo sì jẹ wọ́n níyà ẹ̀ṣẹ̀ wọn.”

11. OLUWA sọ fún mi pé, “Má gbadura pé kí àwọn eniyan wọnyi wà ní alaafia.

Jeremaya 14