21. Kí ni ẹ óo máa wí nígbà tí OLUWA bá mú àwọn tí ẹ fi ṣe ọ̀rẹ́,tí ó fi wọ́n jọba le yín lórí?Ǹjẹ́ ìnira kò ní ba yín, bí ìrora obinrin tí ń rọbí?
22. Bí ẹ bá wí lọ́kàn yín pé,“Kí ló dé tí irú èyí fi dé bá wa?”Ẹ̀ṣẹ̀ yín ni ó pọ̀, ni a fi ká aṣọ ní ìdí yín,tí a sì jẹ yín níyà.
23. Ṣé ó ṣeéṣe kí ará Kuṣi yí àwọ̀ ara rẹ̀ pada?Àbí kí àmọ̀tẹ́kùn fọ tóótòòtóó ara rẹ̀ dànù?Bí ó bá ṣeéṣe, á jẹ́ wí pé ẹ̀yin náà lè hùwà rere;ẹ̀yin tí ibi ṣíṣe ti mọ́ lára.
24. N óo fọn yín ká bí ìyàngbòtí afẹ́fẹ́ láti inú aṣálẹ̀ ń fẹ́ kiri.