11. Wí fún wọn pé àwọn ọlọrun tí kì í ṣe àwọn ni wọ́n dá ọ̀run ati ayé yóo parun láyé ati lábẹ́ ọ̀run.
12. Òun ni ó fi agbára rẹ̀ dá ayé,tí ó fi ọgbọ́n fi ìpìlẹ̀ rẹ̀ sọlẹ̀,tí ó sì fi òye rẹ̀ ta ojú ọ̀run bí aṣọ.
13. Bí ó bá fọhùn, omi á máa rọ́kẹ̀kẹ̀ lójú ọ̀run,ó mú kí ìkùukùu gbéra láti òpin ayé,òun ni ó dá mànàmáná fún òjò,tí ó sì mú afẹ́fẹ́ wá láti ilé ìṣúra rẹ̀.
14. Òmùgọ̀ ni gbogbo eniyan jẹ́, wọn kò sì ní ìmọ̀;gbogbo àwọn alágbẹ̀dẹ wúrà ni àwọn oriṣa wọn dójútì,nítorí pé irọ́ ló wà nídìí àwọn ère wọn;kò sí èémí ninu wọn.
15. Asán ni wọ́n, ohun ìṣìnà sì ni wọ́n;ní àkókò ìjẹníyà wọn, wọn yóo parun ni.
16. Ìpín Jakọbu kò rí bí àwọn wọnyi,nítorí òun ló dá ohun gbogbo,Israẹli sì ni ẹ̀yà tí ó yàn, gẹ́gẹ́ bí ìní rẹ̀;OLUWA àwọn ọmọ ogun ni orúkọ rẹ̀.