Jeremaya 1:11-17 BIBELI MIMỌ (BM)

11. OLUWA bi mí pé, “Jeremaya, kí ni o rí yìí?”Mo dáhùn, pé, “Ọ̀pá igi Alimọndi ni.”

12. OLUWA bá wí fún mi pé, “Òtítọ́ ni ohun tí o rí, nítorí mò ń sọ ọ̀rọ̀ tí mo sọ, n óo sì mú un ṣẹ.”

13. OLUWA tún bi mí lẹẹkeji, ó ní, “Kí ni o rí?”Mo bá dáhùn pé, “Mo rí ìkòkò kan tí ó ń hó lórí iná, ó tẹ̀ láti ìhà àríwá sí ìhà gúsù.”

14. OLUWA bá sọ fún mi pé, “Láti ìhà àríwá ni ibi yóo ti dé bá gbogbo àwọn tí wọn ń gbé ilẹ̀ náà.

15. Nítorí pé mò ń pe gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè tí ó wà ní ìjọba àríwá, èmi OLUWA ni mo sọ bẹ́ẹ̀, àwọn ọba wọn yóo sì tẹ́ ìtẹ́ wọn kalẹ̀ ní ẹnubodè Jerusalẹmu, ati yíká odi gbogbo ìlú Juda.

16. N óo dá wọn lẹ́jọ́ nítorí gbogbo ibi tí wọ́n ti ṣe, tí wọ́n kọ̀ mí sílẹ̀, tí wọn ń sun turari fún àwọn oriṣa, tí wọ́n sì ń bọ ohun tí wọ́n fi ọwọ́ ara wọn ṣe.

17. Ṣugbọn, ìwọ dìde, di àmùrè rẹ, kí o sì sọ gbogbo ohun tí mo pa láṣẹ fún ọ fún wọn. Má jẹ́ kí ẹ̀rù wọn ó bà ọ́, bí bẹ́ẹ̀ kọ́, n óo dẹ́rù bà ọ́ níwájú wọn.

Jeremaya 1