1. Ṣugbọn Ọlọrun ranti Noa, ati gbogbo ẹranko, ati ẹran ọ̀sìn tí ó wà pẹlu rẹ̀ ninu ọkọ̀. Nítorí náà, Ọlọrun mú kí afẹ́fẹ́ kan fẹ́ sórí ilẹ̀, omi náà sì bẹ̀rẹ̀ sí fà.
2. Ọlọrun sé orísun omi tí ó wà lábẹ́ ilẹ̀, ó ti àwọn fèrèsé ojú ọ̀run, òjò náà sì dá.
3. Omi bá bẹ̀rẹ̀ sí fà lórí ilẹ̀. Lẹ́yìn aadọjọ (150) ọjọ́, omi náà fà tán.
4. Ní ọjọ́ kẹtadinlogun oṣù keje, ìdí ọkọ̀ náà kanlẹ̀ lórí òkè Ararati.
5. Omi náà sì ń fà sí i títí di oṣù kẹwaa. Ní ọjọ́ kinni oṣù náà ni ṣóńṣó orí àwọn òkè ńlá hàn síta.