Jẹnẹsisi 46:1-6 BIBELI MIMỌ (BM)

1. Israẹli di gbogbo ohun tí ó ní, ó kó lọ sí Beeriṣeba, ó lọ rúbọ sí Ọlọrun Isaaki, baba rẹ̀.

2. Ọlọrun bá a sọ̀rọ̀ lójú ìran lóru, ó pè é, ó ní, “Jakọbu, Jakọbu.”Ó dáhùn, ó ní, “Èmi nìyí.”

3. Ọlọrun wí pé, “Èmi ni Ọlọrun baba rẹ, má fòyà rárá láti lọ sí Ijipti, nítorí pé n óo sọ ọ́ di orílẹ̀-èdè ńlá níbẹ̀.

4. N óo bá ọ lọ sí Ijipti, n óo sì tún mú ọ pada wá, ọwọ́ Josẹfu ni o óo sì dákẹ́ sí.”

5. Jakọbu bá bẹ̀rẹ̀ ìrìn àjò rẹ̀ láti Beeriṣeba. Àwọn ọmọ rẹ̀ gbé e sinu ọkọ̀ tí Farao fi ranṣẹ sí i pé kí wọ́n fi gbé e wá, wọ́n sì kó àwọn iyawo wọn ati àwọn ọmọ wọn lọ́wọ́ pẹlu wọn.

6. Wọ́n kó àwọn ẹran ọ̀sìn wọn ati gbogbo ohun tí wọ́n ní ní ilẹ̀ Kenaani, wọ́n lọ sí Ijipti.

Jẹnẹsisi 46