Jẹnẹsisi 38:10-23 BIBELI MIMỌ (BM)

10. Ohun tí Onani ń ṣe yìí kò dùn mọ́ Ọlọrun ninu, Ọlọrun bá pa òun náà.

11. Juda bá sọ fún Tamari opó ọmọ rẹ̀ pé, “Wá pada sí ilé baba rẹ kí o lọ máa ṣe opó níbẹ̀ títí tí Ṣela, ọmọ mi yóo fi dàgbà.” Ṣugbọn ọ̀rọ̀ tí Juda sọ yìí kò dé inú rẹ̀ nítorí ẹ̀rù ń bà á pé kí Ṣela náà má kú bí àwọn arakunrin rẹ̀, Tamari bá pada lọ sí ilé baba rẹ̀.

12. Lẹ́yìn ìgbà díẹ̀, aya Juda, tíí ṣe ọmọ Ṣua kú. Nígbà tí Juda ṣọ̀fọ̀ rẹ̀ parí, òun ati Hira ará Adulamu, ọ̀rẹ́ rẹ̀ bá múra, wọ́n lọ sí Timna lọ́dọ̀ àwọn tí wọn ń rẹ́ irun aguntan Juda.

13. Àwọn kan lọ sọ fún Tamari pé baba ọkọ rẹ̀ ń lọ sí Timna láti rẹ́ irun aguntan rẹ̀.

14. Tamari bá bọ́ aṣọ ọ̀fọ̀ kúrò lára, ó fi ìbòjú bo ojú rẹ̀, ó wọ aṣọ tí ó dára, ó bá jókòó lẹ́nu bodè Enaimu tí ó wà lọ́nà Timna; nítorí ó mọ̀ pé Ṣela ti dàgbà, wọn kò sì ṣú òun lópó fún un.

15. Nígbà tí Juda rí Tamari tí ó fi aṣọ bojú, ó rò pé aṣẹ́wó ni.

16. Ó tọ̀ ọ́ lọ níbi tí ó jókòó sí lẹ́bàá ọ̀nà, ó ní, “Wá, jẹ́ kí n bá ọ lòpọ̀,” kò mọ̀ pé opó ọmọ òun ni. Tamari dá a lóhùn, ó ní: “Kí ni o óo fún mi tí mo bá gbà fún ọ?”

17. Juda dáhùn, ó ní, “N óo fi àwọ́nsìn ewúrẹ́ kan ranṣẹ sí ọ láti inú agbo ẹran mi.” Tamari ní, “O níláti fi nǹkankan dógò títí tí o óo fi fi ọmọ ewúrẹ́ náà ranṣẹ.”

18. Juda bá bèèrè pé kí ni ó fẹ́ kí òun fi dógò.Ó dá a lóhùn, ó ní, “Èdìdì rẹ pẹlu okùn rẹ, ati ọ̀pá tí ó wà ní ọwọ́ rẹ.” Juda bá kó wọn fún un, ó sì bá a lòpọ̀, Tamari sì lóyún.

19. Ó dìde, ó bá tirẹ̀ lọ, ó ṣí ìbòjú rẹ̀ kúrò, ó sì tún wọ aṣọ ọ̀fọ̀ rẹ̀.

20. Juda fi àwọ́nsìn ewúrẹ́ náà rán ọ̀rẹ́ rẹ̀, ará Adulamu, sí Tamari, kí ó le bá a gba àwọn ohun tí ó fi dógò lọ́wọ́ rẹ̀, ṣugbọn kò bá a níbẹ̀ mọ́.

21. Ó bi àwọn ọkunrin kan, ará ìlú náà pé, “Níbo ni obinrin aṣẹ́wó tí ó máa ń jókòó ní gbangba lẹ́bàá ọ̀nà Enaimu yìí wà?”Wọ́n dáhùn pé, “Kò fi ìgbà kan sí aṣẹ́wó kankan ní àdúgbò yìí.”

22. Ọ̀rẹ́ Juda bá pada tọ̀ ọ́ lọ, ó ní òun kò rí i, ati pé àwọn ọkunrin tí wọ́n wà níbẹ̀ sọ pé kò fi ìgbà kan sí aṣẹ́wó kankan níbẹ̀.

23. Juda dá a lóhùn, ó ní, “Má wulẹ̀ wá a kiri mọ́, kí àwọn eniyan má baà máa fi wá ṣe yẹ̀yẹ́. Jẹ́ kí ó ṣe àwọn nǹkan ọwọ́ rẹ̀ bí ó bá ti fẹ́, mo ṣá fi àwọ́nsìn ewúrẹ́ tí mo ṣèlérí ranṣẹ, o kò rí i ni.”

Jẹnẹsisi 38