15. Àwọn tí wọ́n jẹ́ ìjòyè ninu àwọn ọmọ Esau nìwọ̀nyí, Lára àwọn ọmọ Elifasi, àkọ́bí Esau, tí Ada bí fún un: Temani, Omari, Sefo, Kenasi.
16. Kora, Gatamu, ati Amaleki. Àwọn wọnyii jẹ́ ọmọ Ada, aya Esau.
17. Lára àwọn ọmọ Reueli, ọmọ Esau, àwọn tí wọ́n jẹ́ ìjòyè ni: Nahati, Sera, Ṣama, ati Misa. Àwọn ni ìjòyè tí wọ́n ṣẹ̀ láti ọ̀dọ̀ Reueli, ní ilẹ̀ Edomu, wọ́n sì jẹ́ ọmọ Basemati, aya Esau.
18. Lára àwọn ọmọ Oholibama, aya Esau: àwọn tí wọ́n jẹ́ ìjòyè ni: Jeuṣi, Jalamu, ati Kora. Àwọn ni ìjòyè tí wọ́n ṣẹ̀ láti ọ̀dọ̀ Oholibama, ọmọ Ana, aya Esau.
19. Wọ́n jẹ́ ọmọ Esau, tí àdàpè rẹ̀ ń jẹ́ Edomu, àwọn sì ni ìjòyè tí wọ́n ti ọ̀dọ̀ rẹ̀ ṣẹ̀.
20. Àwọn ọmọ Seiri ará Hori, tí ń gbé ilẹ̀ náà nìyí: àwọn ọmọ rẹ̀ ni: Lotani, Ṣobali, Sibeoni ati Ana,
21. Diṣoni, Eseri, ati Diṣani, àwọn ni ìjòyè ní ilẹ̀ Hori, wọ́n sì jẹ́ ọmọ Seiri ní ilẹ̀ Edomu.
22. Àwọn ọmọ Lotani ni Hori, ati Hemani, Timna ni arabinrin Lotani.
23. Àwọn ọmọ Ṣobali ni Alfani, Manahati, Ebali, Ṣefo ati Onamu.
24. Àwọn ọmọ Sibeoni ni Aya ati Ana. Ana yìí ni ó rí àwọn ìsun omi gbígbóná láàrin aginjù, níbi tí ó ti ń tọ́jú àwọn kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ Sibeoni, baba rẹ̀.
25. Àwọn ọmọ Ana ni, Diṣoni ati Oholibama.
26. Àwọn ọmọ Diṣoni ni Hemdani, Eṣibani, Itirani, ati Kerani.
27. Àwọn ọmọ Eseri ni: Bilihani, Saafani, ati Akani.
28. Àwọn ọmọ Diṣani ni: Usi ati Arani.
29. Àwọn ìjòyè tí wọ́n ṣẹ̀ lára Hori nìwọ̀nyí: Lotani, Ṣobali, Sibeoni,
30. Diṣoni, Eseri, ati Diṣani. Àwọn ìjòyè ilẹ̀ Hori, gẹ́gẹ́ bí olórí ìdílé ìdílé wọn ní ilẹ̀ Seiri.
31. Àwọn ọba tí wọ́n jẹ ní ilẹ̀ Edomu kí ó tó di pé ẹnikẹ́ni jọba ní ilẹ̀ Israẹli nìwọ̀nyí: