1. Ní ọjọ́ kan, Dina, ọmọbinrin tí Lea bí fún Jakọbu jáde lọ kí àwọn obinrin kan ní ìlú Ṣekemu.
2. Nígbà tí Ṣekemu ọmọ Hamori, ará Hifi, tíí ṣe ọmọ ọba ìlú náà rí i, ó fi ipá mú un, ó sì bá a lòpọ̀ tipátipá.
3. Ọkàn rẹ̀ fà sí Dina ọmọ Jakọbu, ó nífẹ̀ẹ́ rẹ̀, ó sì sọ ọ̀rọ̀ rere fún un.
4. Ṣekemu bá lọ sọ fún Hamori, baba rẹ̀, pé kí ó fẹ́ ọmọbinrin náà fún òun.