Jẹnẹsisi 33:18-20 BIBELI MIMỌ (BM)

18. Nígbà tí ó yá, Jakọbu dé sí Ṣekemu ní ilẹ̀ Kenaani ní alaafia, nígbà tí ó ń pada ti Padani-aramu bọ̀ ó pàgọ́ rẹ̀ siwaju ìlú náà.

19. Ó ra ilẹ̀ ibi tí ó pàgọ́ rẹ̀ sí ní ọgọrun-un (100) gẹsita lọ́wọ́ àwọn ọmọ Hamori, baba Ṣekemu.

20. Ó tẹ́ pẹpẹ kan níbẹ̀, ó sì sọ pẹpẹ náà ní Eli-Ọlọrun-Israẹli.

Jẹnẹsisi 33