Jẹnẹsisi 29:1-3 BIBELI MIMỌ (BM)

1. Jakọbu tún ń bá ìrìn àjò rẹ̀ lọ, nígbà tí ó ṣe, ó dé ilẹ̀ àwọn ará ìlà oòrùn.

2. Bí ó ti gbójú sókè, ó rí kànga kan ninu pápá, ati agbo aguntan mẹta tí wọ́n dùbúlẹ̀ lẹ́gbẹ̀ẹ́ rẹ̀, nítorí pé láti inú kànga yìí ni wọ́n ti ń fún àwọn aguntan náà ní omi mu. Òkúta tí wọ́n sì yí dí ẹnu kànga náà tóbi pupọ.

3. Nígbà tí gbogbo àwọn olùṣọ́-aguntan bá da aguntan wọn dé ìdí kànga yìí ni wọ́n tó ń yí òkúta náà kúrò lẹ́nu kànga. Lẹ́yìn náà, wọn á fún àwọn aguntan wọ́n lómi mu, wọ́n á sì yí òkúta náà pada sẹ́nu kànga.

Jẹnẹsisi 29