1. Ní àkókò kan, ìyàn ńlá kan mú ní ilẹ̀ náà, yàtọ̀ sí ìyàn tí ó mú ní ìgbà Abrahamu. Isaaki bá tọ Abimeleki ọba àwọn ará Filistini lọ ní Gerari.
2. Kí ó tó lọ sí Gerari, Ọlọrun farahàn án, ó sì kìlọ̀ fún un pé kò gbọdọ̀ lọ sí Ijipti, kí ó máa gbé ilẹ̀ tí òun sọ fún un.
3. Ọlọrun ní, “Máa gbé ilẹ̀ yìí, n óo wà pẹlu rẹ, n óo sì bukun ọ, nítorí ìwọ ati àwọn ọmọ rẹ ni n óo fún ní ilẹ̀ wọnyi, n óo sì mú ìlérí mi fún Abrahamu, baba rẹ ṣẹ.
4. N óo sọ àwọn ọmọ rẹ di pupọ bí ìràwọ̀ ojú ọ̀run, n óo sì fún wọn ní ilẹ̀ wọnyi. Nípasẹ̀ wọn ni n óo bukun gbogbo orílẹ̀-èdè ayé,
5. nítorí pé Abrahamu gbọ́ràn sí mi lẹ́nu, ó sì pa gbogbo òfin ati ìlànà mi mọ́ patapata.”
6. Isaaki bá ń gbé Gerari.
7. Nígbà tí àwọn ará ìlú náà bèèrè bí Rebeka ti jẹ́ sí i, ó sọ fún wọn pé arabinrin òun ni. Ẹ̀rù bà á láti jẹ́wọ́ fún wọn pé iyawo òun ni, nítorí ó rò pé àwọn ará ìlú náà lè pa òun nítorí pe Rebeka jẹ́ arẹwà obinrin.