3. Jokiṣani ni baba Ṣeba ati Dedani. Àwọn ọmọ Dedani ni Aṣurimu, Letuṣimu ati Leumimu.
4. Àwọn ọmọ Midiani ni Efai, Eferi, Hanoku, Abida ati Elidaa. Àwọn ni àwọn ìran tó ṣẹ̀ lọ́dọ̀ Ketura.
5. Ṣugbọn Isaaki ni Abrahamu kó gbogbo ohun ìní rẹ̀ fún.
6. Ẹ̀bùn ni ó fún gbogbo ọmọ tí àwọn obinrin mìíràn bí fún un, kí ó tó kú ni ó sì ti ní kí wọ́n jáde kúrò lọ́dọ̀ Isaaki, kí wọ́n lọ máa gbé ní apá ìlà oòrùn ilẹ̀ náà.