12. Ṣugbọn Ọlọrun wí fún Abrahamu pé, “Má ṣe jẹ́ kí inú rẹ bàjẹ́ nítorí ọ̀rọ̀ ọmọ yìí ati ti ẹrubinrin rẹ, ohunkohun tí Sara bá wí fún ọ ni kí o ṣe, nítorí pé orúkọ Isaaki ni wọn yóo fi máa pe atọmọdọmọ rẹ.
13. N óo sọ ọmọ ẹrubinrin náà di orílẹ̀ èdè ńlá pẹlu, nítorí ọmọ rẹ ni òun náà.”
14. Abrahamu bá dìde ní òwúrọ̀ kutukutu, ó mú oúnjẹ ati omi sinu ìgò aláwọ kan, ó dì wọ́n fún Hagari, ó kó wọn kọ́ ọ léjìká, ó fa ọmọ rẹ̀ lé e lọ́wọ́, ó ní kí wọn ó jáde kúrò nílé. Hagari jáde nílé, ó bá ń rìn káàkiri ninu aginjù Beeriṣeba.
15. Nígbà tí omi tán ninu ìgò aláwọ náà, Hagari fi ọmọ náà sílẹ̀ lábẹ́ igbó ṣúúrú kan tí ó wà níbẹ̀.
16. Ó lọ jókòó ní òkèèrè, ó takété sí i, ó tó ìwọ̀n ibi tí ọfà tí eniyan bá ta lè balẹ̀ sí, nítorí ó wí ninu ara rẹ̀ pé, “Má jẹ́ kí n wo àtikú ọmọ mi.”