1. Nígbà kan, àwọn ọba mẹrin kan: Amrafeli, ọba Babiloni, Arioku, ọba Elasari, Kedorilaomeri, ọba Elamu, ati Tidali, ọba Goiimu,
2. gbógun ti Bera, ọba Sodomu, Birisa ọba Gomora, Ṣinabu, ọba Adima, Ṣemeberi, ọba Seboimu ati ọba ìlú Bela (tí ó tún ń jẹ́, Soari).
3. Gbogbo wọn pa àwọn ọmọ ogun wọn pọ̀ ní àfonífojì Sidimu (tí ó tún ń jẹ́ òkun iyọ̀).
4. Fún ọdún mejila gbáko ni àwọn ọba maraarun yìí fi sin Kedorilaomeri, ṣugbọn ní ọdún kẹtala, wọ́n dìtẹ̀.