Jakọbu 2:19-26 BIBELI MIMỌ (BM)

19. Ìwọ gbàgbọ́ pé Ọlọrun kan ní ń bẹ. Ó dára bẹ́ẹ̀. Àwọn ẹ̀mí èṣù pàápàá gbàgbọ́ bẹ́ẹ̀, ìbẹ̀rùbojo sì mú wọn.

20. Ìwọ eniyan lásán! O fẹ́ ẹ̀rí pé igbagbọ ti kò ní iṣẹ́ ninu jẹ́ òkú?

21. Nípa iṣẹ́ kọ́ ni Abrahamu baba wa fi gba ìdáláre, nígbà tí ó fa Isaaki ọmọ rẹ̀ lọ sí orí pẹpẹ ìrúbọ?

22. O rí i pé igbagbọ ń farahàn ninu iṣẹ́ rẹ̀, ati pé iṣẹ́ rẹ̀ ni ó ṣe igbagbọ rẹ̀ ní àṣepé.

23. Èyí ni ó mú kí Ìwé Mímọ́ ṣẹ tí ó sọ pé, “Abrahamu gba Ọlọrun gbọ́, Ọlọrun sì kà á sí olódodo.” A wá pè é ní ọ̀rẹ́ Ọlọrun.

24. Ṣé ẹ wá rí i pé nípa iṣẹ́ ni eniyan fi ń gba ìdáláre, kì í ṣe nípa igbagbọ nìkan?

25. Ṣebí bákan náà ni Rahabu aṣẹ́wó gba ìdáláre nípa iṣẹ́, nígbà tí ó ṣe àwọn amí ní àlejò, tí ó jẹ́ kí wọ́n bá ọ̀nà mìíràn pada lọ?

26. Bí ara láìsí ẹ̀mí ti jẹ́ òkú, bẹ́ẹ̀ ni igbagbọ láìsí iṣẹ́.

Jakọbu 2