3. Talaka tí ń ni aláìní láradàbí òjò líle tí ó ba nǹkan ọ̀gbìn jẹ́.
4. Àwọn tí wọ́n kọ òfin sílẹ̀ni wọ́n máa ń yin àwọn eniyan burúkú,ṣugbọn àwọn tí wọn ń pa òfin mọ́ máa ń dojú ìjà kọ wọ́n.
5. Òye ìdájọ́ òdodo kò yé àwọn eniyan burúkú,ṣugbọn ó yé àwọn tí ń wá OLUWA yékéyéké.
6. Talaka tí ń rìn pẹlu òtítọ́ inúsàn ju ọlọ́rọ̀ tí ń hùwà àgàbàgebè lọ.
7. Ọlọ́gbọ́n ọmọ ni ọmọ tí ó pa òfin mọ́,ṣugbọn ẹni tí ń bá àwọn wọ̀bìà rìn, ń dójúti baba rẹ̀.
8. Ẹni tí ó ń fi kún ọrọ̀ rẹ̀ nípa gbígba èléati èrè jíjẹ ní ọ̀nà èrú,ń kó ọrọ̀ náà jọ fún ẹni tí yóo ṣàánú àwọn talaka.
9. Ẹni tí ó kọ etí dídi sí òfin Ọlọrun,adura rẹ̀ pàápàá yóo di ìríra sí Ọlọ́run.
10. Ẹni tí ó ṣi olódodo lọ́nà lọ sinu ibi,yóo já sinu kòtò tí òun fúnrarẹ̀ gbẹ́ sílẹ̀,ṣugbọn aláìlẹ́bi eniyan yóo jogún ire.
11. Ọlọ́rọ̀ gbọ́n lójú ara rẹ̀,ṣugbọn talaka tí ó gbọ́n yóo rídìí rẹ̀.
12. Nígbà tí olódodo bá borí, àwọn eniyan á yọ̀ ṣẹ̀ṣẹ̀,ṣugbọn nígbà tí ìkà bá dìde, àwọn eniyan á sá pamọ́.