10. Má máa bèèrè pé, “Kí ló dé tí ìgbà àtijọ́ fi dára ju ti ìsinsìnyìí lọ?” Irú ìbéèrè bẹ́ẹ̀ kò mọ́gbọ́n lọ́wọ́.
11. Ọgbọ́n dára bí ogún, a máa ṣe gbogbo eniyan ní anfaani.
12. Nítorí pé bí ọgbọ́n ṣe jẹ́ ààbò, bẹ́ẹ̀ ni owó náà jẹ́ ààbò; anfaani ìmọ̀ ni pé, ọgbọ́n a máa dáàbò bo ọlọ́gbọ́n.
13. Ẹ kíyèsí ọgbọ́n Ọlọrun, nítorí pé, ta ló lè tọ́ ohun tí ó bá dá ní wíwọ́?
14. Máa yọ̀ nígbà tí ó bá dára fún ọ, ṣugbọn nígbà tí nǹkan kò bá dára, máa ranti pé Ọlọrun ló ṣe mejeeji. Nítorí náà, eniyan kò lè mọ ohun tí ń bọ̀ wá ṣẹlẹ̀ lẹ́yìn ọ̀la.
15. Ninu gbogbo ìgbé-ayé asán mi, mo ti rí àwọn nǹkan wọnyi: Mo ti rí olódodo tí ó ṣègbé ninu òdodo rẹ̀, mo sì ti rí eniyan burúkú tí ẹ̀mí rẹ̀ gùn, pẹlu bí ó ti ń ṣe ibi.
16. Má jẹ́ kí òdodo rẹ pọ̀ jù, má sì gbọ́n ní àgbọ́njù; kí ni o fẹ́ pa ara rẹ fún?