21. Ọkunrin náà bá mú mi wá sí ibi gbọ̀ngàn tí ó wà ní ìta, ó mú mi yíká gbogbo igun mẹrẹẹrin gbọ̀ngàn náà, gbọ̀ngàn kéékèèké kọ̀ọ̀kan sì wà ní igun kọ̀ọ̀kan.
22. Ní igun mẹrẹẹrin ni àwọn gbọ̀ngàn kéékèèké yìí wà. Ó gùn ní ogoji igbọnwọ (mita 20), ó sì fẹ̀ ní ọgbọ̀n igbọnwọ (mita 15) àwọn mẹrẹẹrin sì rí bákan náà.
23. Wọ́n fi òkúta kọ́ igun mẹrẹẹrin, ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn yípo. Wọ́n sì kọ́ ibi ìdáná wọn mọ́ ara ògiri.
24. Nígbà náà ni ó wí fún mi pé, “Àwọn ilé ìdáná níbi tí àwọn alufaa tí óo wà níbi pẹpẹ yóo ti máa se ẹran ẹbọ àwọn eniyan mi nìyí.”