26. N óo bá wọn dá majẹmu alaafia, tí yóo jẹ́ majẹmu ayérayé. N óo bukun wọn, n óo jẹ́ kí wọn pọ̀ sí i, n óo sì gbé ilé mímọ́ mi kalẹ̀ sí ààrin wọn títí lae.
27. N óo kọ́ ibùgbé mi sí ààrin wọn, n óo jẹ́ Ọlọrun wọn, wọn yóo sì jẹ́ eniyan mi.
28. Àwọn orílẹ̀-èdè yòókù yóo wá mọ̀ pé èmi OLUWA ni mo ya Israẹli sọ́tọ̀, nígbà tí ibi mímọ́ mi bá wà láàrin wọn títí lae.’ ”