22. “Nítorí náà, OLUWA ní kí n pe ẹ̀yin, ọmọ Israẹli, kí n sọ fun yín pé, òun OLUWA Ọlọrun ní, Kì í ṣe nítorí tiyín ni mo fi ń ṣe ohun tí mò ń ṣe, bíkòṣe nítorí orúkọ mímọ́ mi, tí ẹ̀ ń bàjẹ́ láàrin àwọn orílẹ̀-èdè tí ẹ sálọ.
23. N óo fihàn bí orúkọ ńlá mi, tí ó ti bàjẹ́ láàrin àwọn orílẹ̀-èdè ti jẹ́ mímọ́ tó, àní orúkọ mi tí ẹ bàjẹ́ láàrin àwọn orílẹ̀-èdè tí ẹ wà. Wọn yóo wá mọ̀ pé èmi ni OLUWA Ọlọrun, nígbà tí mo bá ti ipasẹ̀ yín fi bí orúkọ mi ti jẹ́ mímọ́ tó hàn wọ́n.
24. Nítorí pé n óo ko yín jáde láti inú àwọn orílẹ̀-èdè yòókù, n óo gba yín jọ láti gbogbo ilẹ̀ ayé, n óo sì mu yín pada sórí ilẹ̀ yín.
25. N óo wọ́n omi mímọ́ si yín lórí, àìmọ́ yín yóo sì di mímọ́. N óo wẹ̀ yín mọ́ kúrò ninu gbogbo ìbọ̀rìṣà yín.