18. Ojú ọjọ́ yóo ṣókùnkùn ní Tehafinehesi nígbà tí mo bá ṣẹ́ ọ̀pá ìjọba Ijipti, agbára tí ó ń gbéraga sí yóo sì dópin. Ìkùukùu óo bò ó mọ́lẹ̀; wọn óo sì kó àwọn ọmọbinrin rẹ̀ lọ sí ìgbèkùn.
19. Bẹ́ẹ̀ ni n óo ṣe ṣe ìdájọ́ Ijipti, wọn óo wá mọ̀ pé èmi ni OLUWA.”
20. Ní ọjọ́ keje, oṣù kinni ọdún kọkanla, OLUWA bá mi sọ̀rọ̀, ó ní,
21. “Ìwọ ọmọ eniyan, mo ti ṣẹ́ Farao, ọba Ijipti, lápá, a kò sì tíì dí i, kí ọgbẹ́ rẹ̀ fi san, kí ó sì fi lágbára láti gbá idà mú.
22. Nítorí náà, mo lòdì sí Farao, ọba Ijipti. Èmi OLUWA Ọlọrun ní mo sọ bẹ́ẹ̀. N óo ṣẹ́ ẹ ní apá mejeeji: ati èyí tó ṣì lágbára, ati èyí tí ó ti ṣẹ́ tẹ́lẹ̀; n óo sì gbọn idà bọ́ lọ́wọ́ rẹ̀.
23. N óo fọ́n àwọn ará Ijipti ká orílẹ̀-èdè ayé, n óo sì tú wọn káàkiri gbogbo ilẹ̀ ayé.
24. N óo fún ọba Babiloni lágbára, n óo sì fi idà mi lé e lọ́wọ́; ṣugbọn n óo ṣẹ́ Farao lápá; yóo máa kérora níwájú rẹ̀ bí ẹni tí a ṣá lọ́gbẹ́ tí ó ń kú lọ.