12. Nígbà náà ni ẹ̀mí gbé mi dìde, mo sì gbọ́ ìró kan lẹ́yìn mi tí ó dàbí ariwo ìṣẹ̀lẹ̀ ńlá, ó ní, “Ẹ fi ìyìn fún ìfarahàn ògo OLUWA ní ibùgbé rẹ̀.”
13. Ìró ìyẹ́ àwọn ẹ̀dá alààyè náà ni mò ń gbọ́ tí wọn ń kan ara wọn, ati ìró àgbá wọn; ó dàbí ìró ìṣẹ̀lẹ̀ ńlá.
14. Nígbà náà ni ẹ̀mí gbé mi dìde, ó sì gbé mi lọ. Tìbínú-tìbínú ni mo sì fi ń lọ. Ẹ̀mí OLUWA ni ó gbé mi lọ pẹlu agbára.
15. Mo bá dé Teli Abibu lọ́dọ̀ àwọn ìgbèkùn tí wọn ń gbé ẹ̀bá odò Kebari. Ọjọ́ meje ni mo fi wà pẹlu wọn, tí mo jókòó tì wọ́n, tí mò ń wò wọ́n tìyanu-tìyanu.
16. Lẹ́yìn ọjọ́ keje, OLUWA bá mi sọ̀rọ̀, ó ní:
17. “Ọmọ eniyan, mo ti fi ọ́ ṣe olùṣọ́ fún ilé Israẹli. Nígbàkúùgbà tí o bá gbọ́ ohunkohun lẹ́nu mi, o gbọdọ̀ kìlọ̀ fún wọn.
18. Bí mo bá sọ fún eniyan burúkú pé dájúdájú yóo kú, ṣugbọn tí o kò kìlọ̀ fún un pé kí ó yipada kúrò ní ọ̀nà ibi tí ó ń rìn kí ó lè yè, eniyan burúkú náà yóo kú sinu ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀; ṣugbọn lọ́wọ́ rẹ ni n óo ti bèèrè ẹ̀jẹ̀ rẹ̀.