12. N óo sọ ilẹ̀ Ijipti di ahoro patapata, n óo jẹ́ kí àwọn ìlú rẹ̀ di ahoro fún ogoji ọdún. N óo fọ́n àwọn ará Ijipti káàkiri gbogbo ayé, n óo sì tú wọn ká sí ààrin àwọn orílẹ̀-èdè mìíràn.”
13. OLUWA Ọlọrun ní, “Lẹ́yìn ogoji ọdún, n óo kó àwọn ará Ijipti jọ láti gbogbo orílẹ̀-èdè tí mo bá fọ́n wọn ká sí.
14. N óo dá ire wọn pada, n óo kó wọn pada sí ilẹ̀ Patirosi, níbi tí a bí wọn sí. Wọn óo sì wà níbẹ̀ bí ìjọba tí kò lágbára.
15. Òun ni yóo rẹlẹ̀ jù láàrin àwọn orílẹ̀-èdè, kò ní lè gbé ara rẹ̀ ga láàrin àwọn orílẹ̀-èdè mìíràn mọ́. N óo sọ wọ́n di kékeré tóbẹ́ẹ̀ tí wọn kò ní lè jọba lórí orílẹ̀-èdè kankan mọ́.