6. “Nítorí náà, OLUWA Ọlọrun ní, ‘Nítorí pé o ka ara rẹ kún ọlọ́gbọ́n bí àwọn oriṣa,
7. n óo kó àwọn àjèjì wá bá ọ; àwọn tí wọ́n burú jù ninu àwọn orílẹ̀-èdè, wọn óo sì gbógun tì ọ́, wọ́n yóo sì ba ẹwà ati ògo rẹ jẹ́, pẹlu ọgbọ́n rẹ.
8. Wọn óo tì ọ́ sinu ọ̀gbun; o óo sì kú ikú ogun láàrin omi òkun.
9. Ṣé o óo lè sọ pé oriṣa kan ni ọ́ lójú àwọn tí wọ́n bá fẹ́ pa ọ́? Nígbà tí wọ́n bá ń ṣá ọ lọ́gbẹ́, ṣé eniyan ni o óo wá pe ara rẹ àbí oriṣa.
10. Ikú aláìkọlà ni o óo kú lọ́wọ́ àwọn àjèjì, nítorí èmi OLUWA Ọlọrun ni mo sọ bẹ́ẹ̀.’ ”
11. OLUWA tún bá mi sọ̀rọ̀, ó ní,
12. “Ìwọ ọmọ eniyan, kọ orin arò nítorí ohun tí ń bọ̀ wá ṣẹlẹ̀ sí ọba Tire. Wí fún un pé OLUWA Ọlọrun ní: ‘O ti jẹ́ àpẹẹrẹ ìwà pípé, o kún fún ọgbọ́n, o sì lẹ́wà tóbẹ́ẹ̀ tí o kò ní àbùkù kankan.
13. O wà ninu Edẹni, ọgbà Ọlọrun. Gbogbo òkúta olówó iyebíye ni wọ́n fi ṣe ọ́ lọ́ṣọ̀ọ́, àwọn òkúta bíi: kaneliani, topasi, ati jasiperi; kirisolite, bẹrili, ati onikisi; safire, kabọnku ati emeradi. A gbé ọ ka inú àwọn nǹkan ọ̀ṣọ́ wúrà tí a ṣe fún ọ ní ọjọ́ tí a dá ọ.
14. Mo fi kerubu tí a fi àmì òróró yàn tì ọ́. O wà lórí òkè mímọ́ èmi Ọlọrun, o sì ń rìn láàrin àwọn òkúta olówó iyebíye tí ń tàn yinrinyinrin.
15. O péye ninu gbogbo ọ̀nà rẹ, láti ọjọ́ tí wọ́n ti dá ọ títí di ìgbà tí a rí ẹ̀ṣẹ̀ lọ́wọ́ rẹ.
16. Ninu ọpọlọpọ òwò tí ó ń ṣe, o bẹ̀rẹ̀ sí hu ìwà jàgídíjàgan, o sì dẹ́ṣẹ̀, nítorí náà mo lé ọ jáde bí ohun ìríra kúrò lórí òkè Ọlọrun. Kerubu tí ń ṣọ́ ọ sì lé ọ jáde kúrò láàrin àwọn òkúta olówó iyebíye tí ń tàn yinrinyinrin.
17. Ọkàn rẹ kún fún ìgbéraga nítorí pé o lẹ́wà, o ba ọgbọ́n rẹ jẹ́ nítorí ògo rẹ. Mo bì ọ́ lulẹ̀, mo sọ ọ́ di ìran wíwò fún àwọn ọba.