1. OLUWA bá mi sọ̀rọ̀, ó ní,
2. “Ìwọ ọmọ eniyan, kọ orin arò nípa ìlú Tire.
3. Sọ fún ìlú Tire tí ó wà ní etí òkun, tí ń bá gbogbo àwọn tí wọn ń gbé etí òkun ṣòwò. Sọ fún un pé OLUWA Ọlọrun ní:Tire, ìwọ tí ò ń sọ pé,o dára tóbẹ́ẹ̀, tí ẹwà rẹ kò kù síbìkan!
4. Agbami òkun ni bodè rẹ.Àwọn tí wọ́n kọ́ ọ fi ẹwà jíǹkí rẹ.
5. Igi firi láti Seniri ni wọ́n fi ṣe gbogbo ẹ̀gbẹ́ rẹ.Igi kedari láti Lẹbanoni ni wọ́n sì fi ṣe òpó ọkọ̀ rẹ.
6. Igi oaku láti Baṣani ni wọ́n fi ṣe ajẹ̀ rẹ̀Igi sipirẹsi láti erékùṣù Kipru ni wọ́n fi ṣe ilé rẹ.Wọ́n sì fi eyín erin bo inú rẹ̀.