Isikiẹli 26:5-15 BIBELI MIMỌ (BM)

5. Yóo di ibi tí wọn óo máa sá àwọ̀n sí láàrin òkun, nítorí èmi OLUWA Ọlọrun ni mo sọ bẹ́ẹ̀; yóo sì di ìkógun fún àwọn orílẹ̀-èdè mìíràn.

6. Ogun yóo kó àwọn ìlú kéékèèké tí ó wà ní gbogbo agbègbè tí ó yí i ká. Wọn óo wá mọ̀ nígbà náà pé èmi ni OLUWA.”

7. OLUWA Ọlọrun ní, “Ẹ wò ó! N óo mú Nebukadinesari, ọba ńlá Babiloni wá, láti ìhà àríwá, yóo wá gbógun ti Tire. Nebukadinesari, ọba àwọn ọba óo wá, pẹlu ẹṣin ati kẹ̀kẹ́ ogun ati àwọn ẹlẹ́ṣin ati ọpọlọpọ ọmọ ogun.

8. Yóo fi idà pa àwọn ará ìlú kéékèèké tí ó wà ní agbègbè tí ó yí ọ ká. Wọn óo mọ òkítì sí ara odi rẹ, wọn yóo ru erùpẹ̀ jọ, wọn óo fi la ọ̀nà lẹ́yìn odi rẹ, wọn óo sì fi asà borí nígbà tí wọ́n bá ń gun orí odi rẹ bọ̀.

9. Wọn óo fi ìtì igi wó odi rẹ, wọn óo sì fi àáké wó ilé-ìṣọ́ rẹ lulẹ̀.

10. Ẹṣin rẹ̀ óo pọ̀ tóbẹ́ẹ̀ tí eruku ẹsẹ̀ wọn yóo bò ọ́ mọ́lẹ̀ nígbà tí wọ́n bá dé ẹnubodè rẹ, ariwo àwọn ẹlẹ́ṣin rẹ̀ ati ti àwọn kẹ̀kẹ́ ẹrù ati ti kẹ̀kẹ́ ogun rẹ̀ yóo mi odi rẹ tìtì, nígbà tí wọ́n bá dé ẹnubodè rẹ, bí ìgbà tí àwọn ọmọ ogun bá wọ ìlú tí odi rẹ̀ ti wó.

11. Yóo fi pátákò ẹsẹ̀ àwọn ẹṣin rẹ̀ tú gbogbo ilẹ̀ ìgboro rẹ, yóo fi idà pa àwọn eniyan rẹ; yóo sì wó àwọn òpó ńláńlá rẹ lulẹ̀.

12. Yóo kó ọrọ̀ rẹ ati àwọn ọjà tí ò ń tà ní ìkógun. Yóo wó odi rẹ ati àwọn ilé dáradára tí ó wà ninu rẹ lulẹ̀. Yóo ru òkúta, ati igi, ati erùpẹ̀ tí ó wà ninu ìlú rẹ dà sinu òkun.

13. N óo wá fi òpin sí orin kíkọ ninu rẹ; a kò sì ní gbọ́ ohùn dùùrù ninu rẹ mọ́.

14. N óo sì sọ ọ́ di àpáta lásán, o óo di ibi tí wọn óo máa sá àwọ̀n sí; ẹnikẹ́ni kò sì ní tún ọ kọ́ mọ́. Èmi OLUWA Ọlọrun ni mo sọ bẹ́ẹ̀.”

15. OLUWA Ọlọrun sọ fún ìlú Tire pé, “Ǹjẹ́ gbogbo ilẹ̀ tí ó wà létí òkun kò ní mì tìtì nítorí ìṣubú rẹ, nígbà tí àwọn tí wọ́n farapa bá ń kérora, tí a sì pa ọpọlọpọ ní ìpakúpa ninu rẹ?

Isikiẹli 26