12. Lásán ni mò ń ṣe wahala, gbogbo ìpẹtà náà kò ní jóná.
13. Jerusalẹmu, ìṣekúṣe ti dípẹtà sinu rẹ, mo fọ̀ ọ́ títí, ìdọ̀tí kò kúrò ninu rẹ, kò sì ní kúrò mọ́ títí n óo fi bínú sí ọ tẹ́rùn.
14. Èmi OLUWA ni mo sọ bẹ́ẹ̀, n óo sì mú un ṣẹ. Bí mo ti wí ni n óo ṣe, n kò ní dáwọ́ dúró, n kò ní dá ẹnikẹ́ni sí, n kò sì ní yí ọkàn pada. Ìwà ati ìṣe yín ni n óo fi da yín lẹ́jọ́. Èmi OLUWA Ọlọrun ni mo sọ bẹ́ẹ̀.”
15. OLUWA tún bá mi sọ̀rọ̀, ó ní,
16. “Ìwọ ọmọ eniyan, wò ó! Mo ṣetán tí n óo gba ohun tí ń dùn ọ́ ninu lọ́wọ́ rẹ. Lójijì ni n óo gbà á, o kò sì gbọdọ̀ banújẹ́ tabi kí o sọkún, bẹ́ẹ̀ ni omi kò gbọdọ̀ kán sílẹ̀ lójú rẹ.
17. O lè mí ìmí ẹ̀dùn, ṣugbọn a kò gbọdọ̀ gbọ́ ohùn rẹ, o kò sì gbọdọ̀ ṣọ̀fọ̀. Wé lawani mọ́rí, sì wọ bàtà. O kò gbọdọ̀ fi aṣọ bo ẹnu, o kò sì gbọdọ̀ jẹ oúnjẹ ọlọ́fọ̀.”