Isikiẹli 21:15-24 BIBELI MIMỌ (BM)

15. Kí àyà wọn lè já, kí ọpọlọpọ lè kú ní ẹnubodè wọn. Mo ti fi idà tí ń dán lélẹ̀ fún pípa eniyan, ó ń kọ mànà bíi mànàmáná, a sì ti fi epo pa á.

16. Máa pa wọ́n lọ ní ọwọ́ ọ̀tún, ati ní ọwọ́ òsì, níbikíbi tí ó bá sá ti kọjú sí.

17. Èmi náà yóo máa pàtẹ́wọ́, inú tí ń bí mi yóo sì rọ̀, èmi OLUWA ni mo sọ bẹ́ẹ̀.”

18. OLUWA tún bá mi sọ̀rọ̀, ó ní:

19. “Ìwọ ọmọ eniyan, la ọ̀nà meji fún idà ọba Babiloni láti gbà wọ̀lú, kí ọ̀nà mejeeji wá láti ilẹ̀ kan náà. Fi atọ́ka sí oríta níbi tí ọ̀nà ti yà wọ ìlú.

20. La ọ̀nà fún idà kan láti gbà wọ ìlú Raba ní ilẹ̀ Amoni, kí o sì la ọ̀nà mìíràn fún idà láti gbà wọ ilẹ̀ Juda ati ìlú Jerusalẹmu tí a mọ odi yíká.

21. Nítorí pé ọba Babiloni ti dúró sí oríta, ní ibi tí ọ̀nà ti pínyà; ó dúró láti ṣe àyẹ̀wò. Ó mi ọfà, ó bá oriṣa sọ̀rọ̀, ó sì woṣẹ́ lára ẹ̀dọ̀ ẹran.

22. Ọfà ìbò Jerusalẹmu yóo bọ́ sí ọwọ́ ọ̀tún rẹ̀. Yóo kígbe, àwọn eniyan náà yóo sì kígbe sókè. Wọn óo gbé igi tí wọ́n fi ń fọ́ ìlẹ̀kùn ti ìlẹ̀kùn bodè rẹ̀, wọn yóo mọ òkítì sí ara odi rẹ̀, wọn yóo sì mọ ilé ìṣọ́ tì í.

23. Gbogbo ohun tí ó ń ṣe yóo dàbí ẹni tí ń dífá irọ́ lójú àwọn ará ìlú, nítorí pé majẹmu tí wọ́n ti dá yóo ti kì wọ́n láyà; ṣugbọn ọba Babiloni yóo mú wọn ranti ẹ̀ṣẹ̀ wọn, yóo ṣẹgun wọn yóo sì kó wọn lọ.

24. Nítorí náà, èmi OLUWA Ọlọrun, ní, ẹ ti jẹ́ kí n ranti ẹ̀ṣẹ̀ yín, nítorí pé ẹ ti tú àṣírí ẹ̀ṣẹ̀ yín, ninu gbogbo ohun tí ẹ̀ ń ṣe ni ẹ̀ṣẹ̀ yín ti hàn; ogun yóo ko yín nítorí pé ẹ ti mú kí n ranti àwọn ẹ̀ṣẹ̀ yín.

Isikiẹli 21