3. Wí fún wọn pé, OLUWA Ọlọrun ní idì ńlá kan wá sí Lẹbanoni, apá rẹ̀ tóbi, ìrù rẹ̀ sì gùn, ó sì ní ìyẹ́ aláràbarà. Ó bá bà lé ṣóńṣó orí igi kedari kan,
4. ó ṣẹ́ ẹ̀ka rẹ̀ lórí, ó gbé e lọ sí ilẹ̀ àwọn oníṣòwò; ó fi sí ìlú àwọn tí ń ta ọjà.
5. Lẹ́yìn náà, ó mú ninu èso ilẹ̀ náà, ó gbìn ín sí ilẹ̀ kan tí ó lọ́ràá, ní ẹ̀bá odò. Ó gbìn ín bí wọn tíí gbin igi wilo.