1. OLUWA tún bá mi sọ̀rọ̀, ó ní:
2. “Ìwọ ọmọ eniyan, fi nǹkan ìríra tí Jerusalẹmu ń ṣe hàn án,
3. kí o sì sọ fún un pé, OLUWA Ọlọrun sọ nípa Jerusalẹmu pé:“Ilẹ̀ Kenaani ni a bí ọ sí; ibẹ̀ ni orísun rẹ. Ará Amori ni baba rẹ ará Hiti sì ni ìyá rẹ.
4. Bí wọn ṣe bí ọ nìyí: nígbà tí wọ́n bí ọ, wọn kò dá ìwọ́ rẹ, bẹ́ẹ̀ ni wọn kò fi omi wẹ̀ ọ́. Wọn kò fi iyọ̀ pa ọ́ lára, wọn kò sì fi aṣọ wé ọ.
5. Ẹnikẹ́ni kò wò ọ́ lójú, kí ó ṣàánú rẹ, kí ó ṣe ọ̀kan kan ninu àwọn nǹkan wọ̀n-ọn-nì fún ọ. Ṣugbọn wọ́n gbé ọ sọ sinu pápá, nítorí pé wọ́n kórìíra rẹ ní ọjọ́ tí wọ́n bí ọ.
6. “Bí mo tí ń rékọjá lọ lẹ́gbẹ̀ẹ́ rẹ, mo rí ọ tí ò ń ta ẹsẹ̀ ninu ẹ̀jẹ̀. Bí o tí ń yí ninu ẹ̀jẹ̀, mo bá sọ fún ọ pé kí o yè,