21. Nítorí OLUWA Ọlọrun ní, “Báwo ni yóo ti wá burú tó nisinsinyii tí mo rán ìjẹníyà burúkú mẹrin wọnyi sí Jerusalẹmu: ogun, ìyàn, ẹranko burúkú ati àjàkálẹ̀ àrùn láti pa eniyan ati ẹranko run ninu rẹ̀.
22. Sibẹ bí a bá rí àwọn tí wọ́n yè ninu wọn lọkunrin ati lobinrin, tí wọ́n bá wá sọ́dọ̀ rẹ, tí o rí ìwà ati ìṣe wọn, o óo gbà pé mo jàre ní ti ibi tí mo jẹ́ kí ó ṣẹlẹ̀ sí Jerusalẹmu.
23. Wọn yóo jẹ́ ìtùnú fún ọ nígbà tí o bá rí ìwà ati ìṣe wọn, O óo sì mọ̀ pé bí kò bá nídìí, n kò ní ṣe gbogbo ohun tí mo ṣe sí wọn. Èmi OLUWA Ọlọrun ni mo sọ bẹ́ẹ̀.”