1. Àwọn àgbààgbà Israẹli kan tọ̀ mí wá, wọ́n jókòó siwaju mi.
2. OLUWA bá bá mi sọ̀rọ̀,
3. ó ní: “Ìwọ ọmọ eniyan, àwọn ọkunrin wọnyi kó oriṣa wọn lé ọkàn, wọ́n sì gbé ẹrù ẹ̀ṣẹ̀ tí ń múni kọsẹ̀ siwaju wọn. Ṣé wọ́n rò pé n óo dá wọn lóhùn tí wọ́n bá wádìí ọ̀rọ̀ lọ́wọ́ mi?
4. “Nítorí náà, sọ fún wọn pé, èmi OLUWA Ọlọrun ní ẹnikẹ́ni ninu àwọn ọmọ Israẹli tí ó bá kó oriṣa rẹ̀ lé ọkàn tí ó gbé ẹrù ẹ̀ṣẹ̀ tí ń múni kọsẹ̀ siwaju rẹ̀, tí ó wá tọ wolii wá, èmi OLUWA fúnra mi ni n óo dá a lóhùn gẹ́gẹ́ bí ọpọlọpọ oriṣa rẹ̀.
5. Bẹ́ẹ̀ ni n óo ṣe, kí n lè dá ọkàn àwọn ọmọ Israẹli tí wọ́n ṣáko kúrò lọ́dọ̀ mi nítorí oriṣa wọn pada.
6. “Nítorí náà, sọ fún àwọn ọmọ Israẹli pé èmi OLUWA Ọlọrun ní kí wọn ronupiwada, kí wọn pada lẹ́yìn àwọn oriṣa wọn, kí wọn yíjú kúrò lára àwọn nǹkan ìríra tí wọn ń bọ