Isikiẹli 13:8-13 BIBELI MIMỌ (BM)

8. Nítorí náà, OLUWA Ọlọrun ní, “Nítorí ọ̀rọ̀ asán tí ẹ̀ ń sọ, ati ìran èké tí ẹ̀ ń rí, mo lòdì si yín. Bẹ́ẹ̀ ni èmi OLUWA Ọlọrun sọ.

9. N óo jẹ àwọn wolii tí wọn ń ríran èké níyà ati àwọn tí wọn ń woṣẹ́ irọ́. Wọn kò ní bá àwọn eniyan mi péjọ mọ́, tabi kí á kọ orúkọ wọn mọ́ ilé Israẹli, tabi kí wọ́n wọ ilẹ̀ Israẹli mọ́. Ẹ óo sì mọ̀ pé èmi ni OLUWA Ọlọrun.

10. “Nítorí pé wọ́n ti ṣi àwọn eniyan mi lọ́nà wọ́n ń wí fún wọn pé, ‘Alaafia’ nígbà tí kò sí alaafia. Ati pé nígbà tí àwọn eniyan mi ń mọ odi, àwọn wolii wọnyi ń kùn ún ní ọ̀dà funfun.

11. Wí fún àwọn tí wọn ń kun odi náà ní ọ̀dà pé, òjò ńlá ń bọ̀, yìnyín ńlá yóo bọ́, ìjì líle yóo jà.

12. Nígbà tí odi náà bá wó, ǹjẹ́ àwọn eniyan kò ní bi yín pé, ‘Ọ̀dà funfun tí ẹ fi ń kun ara rẹ̀ ńkọ́?’ ”

13. Nítorí náà, OLUWA Ọlọrun ní, “N óo fi ibinu mú kí ìjì líle jà, n óo fi ìrúnú rọ ọ̀wààrà òjò ńlá, n óo mú kí yìnyín ńláńlá bọ́ kí ó pa á run.

Isikiẹli 13