Isikiẹli 11:3-8 BIBELI MIMỌ (BM)

3. Wọ́n ń wí pé, ‘àkókò ilé kíkọ́ kò tíì tó. Ìlú yìí dàbí ìkòkò, àwa sì dàbí ẹran.’

4. Nítorí náà, sọ àsọtẹ́lẹ̀ burúkú nípa wọn, ìwọ ọmọ eniyan, sọ àsọtẹ́lẹ̀.”

5. Ẹ̀mí OLUWA bá bà lé mi, ó sọ fún mi, pé, “OLUWA ní, Èrò yín nìyí, ẹ̀yin ọmọ Israẹli, mo mọ ohun tí ẹ̀ ń rò lọ́kàn,

6. Ẹ ti pa ọpọlọpọ eniyan ní ààrin ìlú yìí; ẹ sì ti da òkú wọn kún gbogbo ìgboro ati òpópónà ìlú.

7. “Nítorí náà, àwọn òkú yín tí ẹ dà sí ààrin ìlú yìí ni ẹran, ìlú yìí sì ni ìkòkò, ṣugbọn n óo mu yín kúrò láàrin rẹ̀.

8. Idà ni ẹ̀ ń bẹ̀rù, idà náà ni n óo sì jẹ́ kí ó pa yín. Èmi OLUWA Ọlọrun ni mo wí bẹ́ẹ̀.

Isikiẹli 11